Toyin Falola
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Àfèrèmọ̀jò kú, ẹnu ìṣà ń ṣọ̀fọ̀
Ọ́pálámbá ọtí eèbọ̀ fọ́, Onígbàsọ ò ri sọ̀
Olukotun lọ, n ò ri mọ́.
Ìwọ Òrẹ́ mi lọ láì wẹ̀yìn wò
Ọjọ́ mẹ́jìlá d’ógún, ó dà bí òní.
Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú afẹ́fẹ́,
Mo rí ẹ̀rù rẹ nínú ojú omi.
Ó dà bíi pé o wà ní ibì kan nítòsí,
Níbi tí ìwọ kò le fi ọwọ́ kàn mi.
Ayé ń yí, ó ń bọ̀, ó ń lọ,
Ṣùgbọ́n iranti rẹ̀ kò fọwọ́ sọ.
Orí mi kún fún ìranti rẹ,
Ọkàn mi sì kún fún ìdárò rẹ pẹ̀lú.
A jọ d’órí omi ayé,
A fi ìfẹ́ rọ̀ mọ́ra.
Ṣùgbọ́n ayé kì í gbà láéláé,
Ó mú ọ lọ, ó fi ọgbẹ́ sọ́kàn
Àràbà ya níjù
Ẹja ńlá lọ lómi.
Mo wá máa sọ̀rọ̀ sí afẹ́fẹ́,
Kí ó gbóhùn mi dé ọ̀dọ̀ rẹ
Ojú rẹ wá di
Ohun mò ń gbé inú àwòrán wò
Haa, igi oko dá
Ẹyẹ oko ti gbéra sọ.
Òrẹ́ mi, ìwọ t’ó lọ,
Ìrántí rẹ̀ kò ní ṣí fún mi.
Mo máa rántí ọ nínú ìrọ̀lẹ̀,
Nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òòrùn bá n rẹ̀wà
Nígbà tí ọjọ́ bá kanri
Ìrántí rẹ dúró ṣinṣin.
Sùn-un re
Ní ilé ayé tí kò ní ikù.
Ṣùgbọ́n má gbàgbé mí, òrẹ́ mi,
Tí mo bá dé, jọ̀wọ́, ṣe mi káàbọ̀.
Káa tó rí Erin, ó di igbó
Káa tó rí Ẹ̀fọ̀n, ó di ọ̀dàn
Káa tó rí Lèkélèké ẹyẹ oòṣà ńlá
Ó di dandan kaa délé ẹfun
Ó di gbéré
Ó di bí ẹni bá jọ ni
Ìpàdé di ọjọ́ ìkẹyìn
Ìpàdé di ọjọ́ ìdájọ́ ńlá.
Please join us at the inaugural Professor Olukotun’s memorial lecture at Lead City University on Tuesday, March 18, 2025, at 10.30 AM.
Ó wuyì púpọ̀. Iṣẹ́ àti ìṣe tí ọmọ Olùkọ̀tun fi sílẹ̀ kí Elédùeà má jẹ́ kí ó parun.
Bí ọdẹ bá kú
Níṣe ní wọ́n m’áféré bọnu
Èkútú á máa já tòòòò
Ọdẹ náà ni ṣe Ìrèmọ̀jé
Ìṣípà là á fí ṣorò lẹ́yìn àgbà ọdẹ
Bí àgbà Ọ̀jọ̀gbọ́n bá ṣípò padà
Bí àgbà Ọ̀jìnmí Ọ̀jọ̀gbọ́n
Bá fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣorò
Kò léèwọ̀
Tóyìn ọmọ Fálọlá bọ́ ságbo
Kó o fi winrín winrìn ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ ṣorò
F’ Áyọ̀ ọmọ Olúkọ̀tún
A kìí sọ́ fónígẹ̀gẹ̀ gbé tọ̀fun rẹ̀ mì
Tóyìn ọmọ Fálọlá ọ̀rẹ́ minú Ayọ̀
Ìwọ lo lọ̀rọ̀
Ìwọ lo lagbo
Kò sẹ́ni tí pohùn mágogo lẹ́nu
Ire o