Prof Falola Báa bá wẹ̀kun ayé

Lateef Raji

Béèyàn ò bá fàná ṣòfò

Kò níí fèní ṣẹ̀sín

Báa bá wẹ̀kun ayé

Tá à rì

Táa gun gègéle

Tá à já bọ́

Tí a rin pẹ̀tẹ́lẹ̀ ilẹ̀

Tá à rá

Tá ṣe kòńgẹ́ afẹ́fẹ́

Tó pa ọ̀pọ̀

Táa yè é

Báa bá rántí orí, rántí ẹlẹ́dàá

Tó gbeni, sààbò ẹni

Báa bá gbè fórí, fìyìn fẸ́lẹ́dàá

Kò léèwọ̀.

“Ayé lọjà”

Ọ̀rọ̀ àwọn bàbá wa

Báa bá wáyé nájà jèrè

Kì í ṣagbára

Ọ̀pò ló wáyé

Wà láàyè bí aláìsí

Orí tó gbeni

Lè ṣàtakò ẹni

Orí tí yóò gbè irú yín

Ló jẹ́ ẹ nájà jèrè dọjọ́ alẹ́.

Bẹ́dàá bá ronú jinlẹ̀ áá mọ̀

Ká tó dáyé laláyé ti ń ṣayé

Nígbà táa dáyé, à ń bá wọn ṣayé

Ẹ̀yín bá wọn ṣayé

Ẹ tún ń ṣayé ire

Báà bá sí láyé, aláyé a ṣayé

Ayé ò dúró

Lèrò yín ò fi dúró

Lórí à ti gún ayé lẹ́ fi dọlọ́pọ̀ èèyàn

Ayé ti ń kọrin,

Kẹ́ẹ tó dolórin

Ohùn ọ̀tọ̀ lorin yín fi dùn yàtọ̀ létí ọmọ ènìyàn

Ayé ti ń rọ́tàn

Kẹ́ e tó donítàn

Ìtan ò dùn bíi ká mò ọ́ rọ́

Orin dùn lẹ́nu baba

Ìtán dùn lẹ́nu àgbà òpìtàn

Bọ́rò ayé bá dàrú

Ẹ pọmọ Fálọlá kó fìtàn tún un tò

Ibi bàtà gbé ń tani lẹ́sẹ̀

Ẹní wọ̀ ọ́, ló mọ̀

Bó bá di ọ̀rò ogun Ìjàyè

Ògúnmọ́lá ni wón ní á bi

Bọ́rọ̀ bá dọ̀rọ̀ ìlọsíwájú ayé

Baba rere ni ẹ jẹ́ á bi léèrè

Ẹní mọ̀ ọ́ wò bí ọlọ́mọ ò sí.

Baba mọ̀ràn, mọ̀tàn, mẹ̀tọ́, mètò

Niná ọlá, iyì baba

Fi ń fojoójúmọ́ gòkè

Ọlá ìbí wá ń kún

Ọlá ibi a gbé bí baba

Ẹ wáá di Ọmọ́kọ́lá

Tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fojoójúmọ́ yàn

Béèyàn ò bá fàná ṣòfò

Kò níí fèní ṣẹ̀sín

Ẹ ẹ̀ fi àná yín ṣòfò

Lẹ fi di funfun inú ẹyẹlé

Tọ́mọ aráyé ń fojoójúmọ́ wá kiri

Aṣọ àlà tí ẹ wọ̀

Ọmọ aráyé ò ní da epo sí i.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *